Genesis 42:27 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nígbà tí wọ́n dé ibi tí wọn yóo sùn lálẹ́ ọjọ́ náà, ọ̀kan ninu wọn tú àpò rẹ̀ láti fún kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀ ní oúnjẹ, ó bá rí owó rẹ̀ tí wọ́n dì sí ẹnu àpò rẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Bi ọkan ninu wọn si ti tú àpo rẹ̀ ni ile-èro lati fun kẹtẹkẹtẹ rẹ̀ li onjẹ, o kofiri owo rẹ̀; si wò o, o wà li ẹnu àpo rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Níbi tí wọ́n ti dúró láti sùn lóru ọjọ́ náà, ọ̀kan nínú wọn tú àpò rẹ̀ láti mú oúnjẹ fún kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀, ó sì rí owó rẹ̀ ní ẹnu àpò rẹ̀.