Genesis 42:28 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ó wí fún àwọn arakunrin rẹ̀ pé, “Wọ́n dá owó mi pada, òun nìyí lẹ́nu àpò mi yìí.” Nígbà tí wọ́n gbọ́ bẹ́ẹ̀, ẹ̀rù bà wọ́n gidigidi, wọ́n ń wo ara wọn lójú, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí gbọ̀n, wọ́n ní, “Irú kí ni Ọlọrun ṣe sí wa yìí?”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O si wi fun awọn arakunrin rẹ̀ pe, Nwọn mú owo mi pada; si wò o, o tilẹ wà li àpo mi: àiya si fò wọn, ẹ̀ru si bà wọn, nwọn nwi fun ara wọn pe, Kili eyiti Ọlọrun ṣe si wa yi?
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ó sì wí fún àwọn arákùnrin rẹ̀ pé, “a ti dá owó mi padà, òun nìyí ní ẹnu àpò mi.” Ẹ̀rù bà wọ́n, wọ́n sì ń gbọ̀n, wọ́n sì wí pé, “Èwo nìyí tí Ọlọ́run ṣe sí wa yìí.”