Genesis 42:34 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Kí á mú àbúrò wa patapata wá fún òun, nígbà náà ni òun yóo tó mọ̀ pé a kì í ṣe amí, ati pé olóòótọ́ eniyan ni wá, òun óo sì dá arakunrin wa pada fún wa, a óo sì ní anfaani láti máa ṣòwò ní ilẹ̀ Kenaani.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ẹ si mú arakunrin nyin abikẹhin nì tọ̀ mi wá: nigbana li emi o mọ̀ pe ẹnyin ki iṣe amí, bikoṣe olõtọ enia: emi o si fi arakunrin nyin lé nyin lọwọ, ẹnyin o si ma ṣòwo ni ilẹ yi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣùgbọ́n ẹ mú arákùnrin yín tí ó kéré jù lọ wá fún mi kí n le mọ̀ pé dájúdájú ẹ kì í ṣe ayọ́lẹ̀wò bí kò ṣe ènìyàn tòótọ́. Nígbà náà ni n ó mú arákùnrin yín pada fún un yín, lẹ́yìn náà ẹ le máa wá ṣe òwò bí ó ti wù yín ní ilẹ̀ yìí.’ ”