Genesis 42:36 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Jakọbu baba wọn bá sọ fún wọn, ó ní, “Ẹ ti jẹ́ kí n ṣòfò àwọn ọmọ mi: Josẹfu ti kú, Simeoni kò sí mọ́, ẹ tún fẹ́ mú Bẹnjamini lọ. Èmi nìkan ni gbogbo èyí ṣẹlẹ̀ sí tán!”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Jakobu baba wọn si wi fun wọn pe, Emi li ẹnyin gbà li ọmọ: Josefu kò sí; Simeoni kò si sí; ẹ si nfẹ́ mú Benjamini lọ: lara mi ni gbogbo nkan wọnyi pọ̀ si.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Jákọ́bù bàbá wọn wí fún wọn pé, “Ẹ ti mú mi pàdánù àwọn ọmọ mi. N kò rí Jósẹ́fù mọ́, bẹ́ẹ̀ ni n ò kò sì rí Símónì náà mọ. Ẹ sì tún fẹ́ mú Bẹ́ńjámínì lọ! Èmi ni gbogbo ohun búburú yìí wá ń ṣẹlẹ̀ sí.”