Genesis 42:6 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ní gbogbo àkókò yìí, Josẹfu ni gomina ilẹ̀ Ijipti, òun ni ó ń ta ọkà fún àwọn eniyan láti gbogbo orílẹ̀-èdè. Nígbà tí àwọn arakunrin rẹ̀ dé, wọ́n kí i, wọ́n wólẹ̀ níwájú rẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Josefu li o si ṣe balẹ ilẹ na, on li o ntà fun gbogbo awọn enia ilẹ na; awọn arakunrin Josefu si wá, nwọn si tẹ̀ ori wọn ba fun u, nwọn dojubolẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nisinsin yìí, Jósẹ́fù ni alábojútó fún gbogbo ilẹ̀ Éjíbítì, òun sì ni ó ń bojú tó ọkà títà fún gbogbo ènìyàn ìlú náà. Nítorí náà nígbà tí àwọn arákùnrin Jóṣẹ́fù dé, wọ́n tẹríba, wọ́n sì foríbalẹ̀ fún Jósẹ́fù.