Genesis 43:30 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Josẹfu bá yára jáde kúrò lọ́dọ̀ wọn nítorí pé ọkàn rẹ̀ fà sí àbúrò rẹ̀, orí rẹ̀ sì wú, ó wá ibìkan láti lọ sọkún. Ó bá wọ yàrá rẹ̀, ó lọ sọkún níbẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Josefu si yara; nitori ti inu yọ́ ọ si aburo rẹ̀: o wá ibi ti yio gbé sọkun; o si bọ́ si iyẹwu, o si sọkun nibẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ọkàn rẹ̀ sì fà sí i gidigidi nígbà tí ó rí arákùnrin rẹ̀, nítorí náà Jósẹ́fù yára jáde láti wá ibi tí ó ti le sunkún. Ó lọ sí iyàrá rẹ̀, ó sì sunkún níbẹ̀.