Genesis 43:32 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Wọ́n gbé oúnjẹ tirẹ̀ kalẹ̀ lọ́tọ̀, ti àwọn arakunrin rẹ̀ lọ́tọ̀, ati ti àwọn ará Ijipti tí wọn ń bá a jẹun lọ́tọ̀, nítorí pé ìríra ni ó jẹ́ fún àwọn ará Ijipti láti bá àwọn Heberu jẹun pọ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nwọn si gbé tirẹ̀ kalẹ fun u lọ̀tọ, ati fun wọn lọ̀tọ, ati fun awọn ara Egipti ti o mbá a jẹun lọ̀tọ; nitori ti awọn ara Egipti kò gbọdọ bá awọn enia Heberu jẹun; nitori irira ni fun awọn ara Egipti.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Wọ́n gbé oúnjẹ tirẹ̀ fun-un lọ́tọ̀, àti fún àwọn ará Éjíbítì tí ó wá ba jẹun náà lọ́tọ̀, nítorí ará Éjíbítì kò le bá ará Ébérù jẹun nítorí ìríra pátapáta ló jẹ́ fún àwọn Éjíbítì.