Genesis 43:34 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Láti orí tabili Josẹfu ni wọ́n ti bu oúnjẹ fún olukuluku, ṣugbọn oúnjẹ ti Bẹnjamini tó ìlọ́po marun-un ti ẹnìkọ̀ọ̀kan wọn. Wọ́n bá a jẹ, wọ́n mu, wọ́n sì bá a ṣe àríyá.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O si bù onjẹ fun wọn lati iwaju rẹ̀ lọ: ṣugbọn onjẹ Benjamini jù ti ẹnikẹni wọn lẹrinmarun. Nwọn si mu, nwọn si bá a ṣe ariya.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
A sì bu oúnjẹ fún wọn láti orí tábìlì Jósẹ́fù. Oúnjẹ Bẹ́ńjámínì sì tó ìlọ́po márùn-ùn ti àwọn tókù. Wọ́n ń jẹ, wọ́n sì ń mu lọ́dọ̀ rẹ̀ láì sí ìdíwọ́.