Genesis 43:7 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Wọ́n dá a lóhùn pé, “Kò sí ohun tí ọkunrin náà kò bi wá tán nípa ará ati ẹbí wa, ó ní, ‘Ǹjẹ́ baba yín wà láàyè? Ǹjẹ́ ẹ tún ní arakunrin mìíràn?’ Àwọn ìbéèrè tí ó ń bèèrè ni ó mú kí á sọ ohun tí a sọ fún un. Báwo ni a ṣe lè mọ̀ pé yóo sọ pé kí á mú àbúrò wa wá?”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nwọn si wipe, ọkunrin na bère timọtimọ niti awa tikara wa, ati niti ibatan wa, wipe, Baba nyin wà sibẹ̀? ẹnyin li arakunrin miran? awa si wi fun u bi ọ̀rọ wọnyi: awa o ti ṣe le mọ̀ daju pe yio wipe, Mú arakunrin nyin sọkalẹ wá?
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Wọ́n dáhùn pé, “Ọkùnrin náà fi pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ wádìí lọ́wọ́ wa nípa ìdílé wa àti àwa fúnra wa. Ó béèrè pé, ‘Ṣe bàbá yín sì wà láàyè?’ Ǹjẹ́ ẹ tún ní arákùnrin mìíràn?: A kàn dáhùn ìbéèrè rẹ̀ ni. Báwo ni a ṣe le mọ̀ pé yóò wí pé, ‘Ẹ mú arákùnrin yín wá’?”