Genesis 44:1 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Josẹfu pàṣẹ fún alabojuto ilé rẹ̀, ó ní, “Ẹ di ọkà kún àpò àwọn ọkunrin wọnyi, bí wọ́n bá ti lè rù tó, kí ẹ sì fi owó olukuluku wọn sí ẹnu àpò rẹ̀,
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O SI fi aṣẹ fun iriju ile rẹ̀, wipe, Fi onjẹ kún inu àpo awọn ọkunrin wọnyi, ìwọn ti nwọn ba le rù, ki o si fi owo olukuluku si ẹnu àpo rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà náà ni Jósẹ́fù pàṣẹ fún ìránṣẹ́ rẹ̀ pé, “Di oúnjẹ kún inú àpò àwọn ọkùnrin náà tó ìwọ̀n èyí tí wọ́n le rù, kí o sì mú owó olúkúlukù àwọn ọkùnrin náà padà sí ẹnu àpò rẹ̀.