Genesis 44:12 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Iranṣẹ náà bá bẹ̀rẹ̀ sí wo àpò wọn, ó bẹ̀rẹ̀ lórí àpò èyí àgbà patapata, títí dé orí ti àbíkẹ́yìn wọn, wọ́n bá ife náà ninu ẹrù Bẹnjamini.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O si nwá a kiri, o bẹ̀rẹ lati ẹgbọ́n wá, o si pin lọdọ abikẹhin: a si ri ago na ninu àpo Benjamini.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà náà ni ìránṣẹ́ náà bẹ̀rẹ̀ sí ní í wá a, bẹ̀rẹ̀ láti orí ẹ̀gbọ́n títí lọ sórí àbúrò pátapáta. Ó sì rí kọ́ọ́bù náà nínú àpò ti Bẹ́ńjámínì.