Genesis 44:16 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Juda dá a lóhùn, ó ní, “Kí ni a rí tí a lè wí fún ọ, oluwa mi? Ọ̀rọ̀ wo ni ó lè dùn lẹ́nu wa? Ọṣẹ wo ni a lè fi wẹ̀, tí a fi lè mọ́? Ọlọrun ti rí ẹ̀bi àwa iranṣẹ rẹ. Wò ó, a di ẹrú rẹ, oluwa mi, ati àwa ati ẹni tí wọ́n bá ife náà lọ́wọ́ rẹ̀.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Judah si wipe, Kili a o wi fun oluwa mi? kili a o fọ̀? tabi awa o ti ṣe wẹ̀ ara wa mọ́? Ọlọrun ti hú ẹ̀ṣẹ awọn iranṣẹ rẹ jade: wò o, awa di ẹrú oluwa mi, ati awa, ati ẹniti a ri ago na li ọwọ́ rẹ̀ pẹlu.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Júdà dáhùn pé, “Kín ni à bá sọ fún olúwa mi? Báwo ni a ṣe lè wẹ ara wa mọ́? Ọlọ́run ti tú àsírí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀, a ti di ẹrú olúwa à mi báyìí-àwa fúnra wa àti ẹni náà tí a rí kọ́ọ̀bù lọ́wọ́ rẹ̀.”