Genesis 44:18 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Juda bá tọ̀ ọ́ lọ, ó ní, “Jọ̀wọ́, oluwa mi, jẹ́ kí n sọ gbolohun ọ̀rọ̀ kan, má jẹ́ kí inú bí ọ sí èmi, iranṣẹ rẹ, nítorí kò sí ìyàtọ̀, bíi Farao ni o rí.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbana ni Judah sunmọ ọdọ rẹ̀, o si wipe, Oluwa mi, emi bẹ̀ ọ, jẹ ki iranṣẹ rẹ ki o sọ gbolohùn ọ̀rọ kan li eti oluwa mi, ki o máṣe binu si iranṣẹ rẹ; bi Farao tikalarẹ̀ ni iwọ sá ri.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà náà ni Júdà sún mọ́ ọ̀dọ̀ rẹ̀, ó sì wí pé, “Jọ̀wọ́ olúwa mi, jẹ́ kí ìránṣẹ́ rẹ kí ó sọ ọ̀rọ̀ kan fún olúwa mi, má ṣe bínú sí ìránṣẹ́ rẹ bí ó tilẹ̀ jẹ́ wí pé ìwọ pẹ̀lú láṣẹ bí i ti Fáráò.