Genesis 44:2 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
kí ẹ wá fi ife fadaka mi sí ẹnu àpò èyí àbíkẹ́yìn wọn, pẹlu owó tí ó fi ra ọkà.” Ọkunrin náà sì ṣe gẹ́gẹ́ bí Josẹfu ti pàṣẹ fún un.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ki o si fi ago mi, ago fadaka nì, si ẹnu àpo abikẹhin, ati owo ọkà rẹ̀. O si ṣe gẹgẹ bi ọ̀rọ ti Josefu ti sọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà náà ni kí o mú kọ́ọ̀bù idẹ mi sí ẹnu àpò èyí tí ó jẹ́ àbíkẹ́yìn nínú wọn pẹ̀lú owó tí ó fi ra ọkà,” ó sì ṣe bí Jósẹ́fù ti sọ.