Genesis 44:20 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
A sì dá oluwa mi lóhùn pé, ‘A ní baba, ó ti di arúgbó, a sì ní arakunrin kan pẹlu, tí baba yìí fi arúgbó ara bí, ati pé ẹ̀gbọ́n rẹ̀ ti kú, òun nìkan ṣoṣo ni ó kù lọ́mọ ìyá tirẹ̀, baba rẹ̀ sì fẹ́ràn rẹ̀.’
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Awa si wi fun oluwa mi pe, Awa ní baba, arugbo, ati ọmọ kan li ogbologbo rẹ̀, abikẹhin; arakunrin rẹ̀ si kú, on nikanṣoṣo li o si kù li ọmọ iya rẹ̀, baba rẹ̀ si fẹ́ ẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
A sì dáhùn pé, ‘A ni baba tí ó ti darúgbó, ọmọkùnrin kan sì wà pẹ̀lú tí a bí fún un ní ọjọ́ ogbó rẹ̀. Ẹ̀gbọ́n rẹ̀ ti kú, òun nìkan sì ni ó kù nínú àwọn ọmọ ìyá rẹ̀, baba rẹ̀ sì fẹ́ràn an rẹ̀.’