Genesis 44:26 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
a wí fún un pé, a kò ní lọ, àfi bí arakunrin wa bá tẹ̀lé wa, nítorí pé a kò ní rí ojú rẹ nílẹ̀ bí kò bá bá wa wá.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Awa si wipe, Awa kò le sọkalẹ lọ: bi arakunrin wa abikẹhin ba pẹlu wa, njẹ awa o sọkalẹ lọ; nitori ti awa ki o le ri oju ọkunrin na, bikoṣepe arakunrin wa abikẹhin ba pẹlu wa.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣùgbọ́n a wí pe, ‘Àwa kò le è padà lọ, àyàfi bí àbúrò wa pátapáta yóò bá bá wa lọ. A kò le è rí ojú ọkùnrin náà àyàfi tí àbúrò wa bá lọ pẹ̀lú wa.’