Genesis 44:33 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nígbà tí ọ̀rọ̀ wá rí bí ó ti rí yìí, oluwa mi, jọ̀wọ́, jẹ́ kí èmi di ẹrú rẹ dípò ọmọdekunrin yìí, jẹ́ kí òun máa bá àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ̀ pada lọ.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Njẹ nisisiyi emi bẹ̀ ọ, jẹ ki iranṣẹ rẹ ki o joko ni ipò ọmọde na li ẹrú fun oluwa mi; ki o si jẹ ki ọmọde na ki o bá awọn arakunrin rẹ̀ goke lọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Nítorí náà, jẹ́ kí ìránṣẹ́ rẹ kí ó dúró ní ìhín lọ́dọ̀ olúwa à mi bí ẹrú dípò ọmọ náà. Kí ọmọ náà bá àwọn arákùnrin rẹ̀ padà.