Genesis 44:7 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Wọ́n dá a lóhùn, wọ́n ní, “Èéṣe tí o fi ń sọ̀rọ̀ sí wa báyìí? Kí á má rí i, pé àwa iranṣẹ rẹ ṣe ohun tí ó jọ bẹ́ẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nwọn si wi fun u pe, Ẽṣe ti oluwa mi fi sọ irú ọ̀rọ wọnyi? Ki a má ri pe awọn ọmọ-ọdọ rẹ ṣe bi irú nkan wọnyi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣùgbọ́n wọ́n dá a lóhùn pé, “Kín ló dé tí olúwa mi sọ irú nǹkan wọ̀nyí? Ká má rí i! Àwọn ìránṣẹ́ rẹ kò le ṣe irú nǹkan bẹ́ẹ̀!