Genesis 45:1 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Josẹfu kò lè mú ọ̀rọ̀ yìí mọ́ra mọ́ lójú gbogbo àwọn tí wọ́n wà lọ́dọ̀ rẹ̀, ó bá kígbe, ó ní, “Gbogbo yín patapata, ẹ jáde kúrò lọ́dọ̀ mi.” Nítorí náà, kò sí ẹnikẹ́ni lọ́dọ̀ Josẹfu nígbà tí ó fi ara rẹ̀ han àwọn arakunrin rẹ̀ pé òun ni Josẹfu.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
NIGBANA ni Josefu kò le mu oju dá mọ́ niwaju gbogbo awọn ti o duro tì i; o si kigbe pe, Ẹ mu ki gbogbo enia ki o jade kuro lọdọ mi. Ẹnikẹni kò si duro tì i, nigbati Josefu sọ ara rẹ̀ di mimọ̀ fun awọn arakunrin rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Jósẹ́fù kò sì le è pa á mọ́ra mọ́ níwájú gbogbo àwọn tí ó dúró tì í. Ó sì sunkún sókè tó bẹ́ẹ̀ tí àwọn tí ó wà ní àyíká gbọ́ ohun ẹkún rẹ̀. “Jẹ́ kí gbogbo ènìyàn kúrò ní ọ̀dọ̀ mi.” Kò sì sí ẹnikẹ́ni lọ́dọ̀ rẹ̀ nígbà tí ó fi ara rẹ̀ hàn fún àwọn arákùnrin rẹ̀.