Genesis 45:10 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ẹ sọ fún un pé mo sọ pé kí ó wá máa gbé ní ilẹ̀ Goṣeni nítòsí mi, òun ati àwọn ọmọ rẹ̀, ati àwọn ọmọ ọmọ rẹ̀, ati agbo mààlúù rẹ̀, ati ohun gbogbo tí ó ní.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Iwọ o si joko ni ilẹ Goṣeni, iwọ o si wà leti ọdọ mi, iwọ, ati awọn ọmọ rẹ, ati awọn ọmọ ọmọ rẹ, ati ọwọ-ẹran rẹ, ati ọwọ́-malu rẹ, ati ohun gbogbo ti iwọ ní.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ìwọ yóò gbé ní agbégbé Gósénì, ìwọ kì yóò jìnnà sí mi-ìwọ, àwọn ọmọ rẹ àti àwọn ọmọ-ọmọ rẹ, àwọn agbo ẹran rẹ àti agbo màlúù rẹ àti gbogbo ohun tí ìwọ ní.