Genesis 45:27 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ṣugbọn nígbà tí ó gbọ́ gbogbo ohun tí Josẹfu wí fún wọn, tí ó tún rí kẹ̀kẹ́ ẹlẹ́ṣin tí Josẹfu fi ranṣẹ pé kí wọ́n fi gbé òun wá, ara rẹ̀ wálẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nwọn si sọ ọ̀rọ Josefu gbogbo fun u, ti o wi fun wọn: nigbati o si ri kẹkẹ́-ẹrù ti Josefu rán wá lati fi mú u lọ, ọkàn Jakobu baba wọn sọji:
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣùgbọ́n nígbà tí wọ́n sọ ohun gbogbo tí Jósẹ́fù ti sọ fún wọn fún un tí ó sì rí kẹ̀kẹ́ ẹrù tí Jósẹ́fù fi ránṣẹ́ láti gbé e padà wá, iyè Jákọ́bù, baba wọn ṣọ.