Genesis 46:15 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
(Àwọn ni ọmọ tí Lea bí fún Jakọbu ní Padani-aramu ati Dina, ọmọ rẹ̀ obinrin.) Gbogbo àwọn ọmọ rẹ̀ lọkunrin ati lobinrin jẹ́ mẹtalelọgbọn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Awọn wọnyi li awọn ọmọ Lea, ti o bí fun Jakobu ni Padan-aramu, pẹlu Dina ọmọbinrin rẹ̀: gbogbo ọkàn awọn ọmọ rẹ̀ ọkunrin ati awọn ọmọ rẹ̀ obinrin, o jẹ́ mẹtalelọgbọ̀n.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Wọ̀nyí ni àwọn ọmọkùnrin Líà tí ó bí fún Jákọ́bù ní Padani-Árámù yàtọ̀ fún Dínà ọmọbìnrin rẹ̀. Àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ àti ọmọbìnrin rẹ̀ wọ̀nyí jẹ́ mẹ́talélọ́gbọ̀n. (35) lápapọ̀.