Genesis 46:27 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Àwọn ọmọ tí Josẹfu bí ní Ijipti jẹ́ meji. Gbogbo eniyan tí ó ti ìdílé Jakọbu jáde lọ sí Ijipti patapata wá jẹ́ aadọrin.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ati awọn ọmọ Josefu ti a bí fun u ni Egipti jẹ́ ọkàn meji; gbogbo ọkàn ile Jakobu, ti o wá si ilẹ Egipti jẹ́ ãdọrin ọkàn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Pẹ̀lú àwọn ọmọkùnrin méjì tí a bí fún Jósẹ́fù ní Éjíbítì àwọn ará ilé Jákọ́bù tí ó lọ sí Éjíbítì jẹ́ àádọ́rin (70) lápapọ̀