Genesis 46:34 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
kí wọ́n dá a lóhùn pé, ẹran ọ̀sìn ni àwọn ti ń tọ́jú láti ìgbà èwe àwọn títí di ìsinsìnyìí, ati àwọn ati àwọn baba àwọn, kí ó lè jẹ́ kí wọ́n máa gbé ilẹ̀ Goṣeni, nítorí pé ìríra patapata ni gbogbo darandaran jẹ́ fún àwọn ará Ijipti.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ki ẹnyin ki o wipe, Òwo awọn iranṣẹ rẹ li ẹran sisìn lati ìgba ewe wa wá titi o fi di isisiyi, ati awa, ati awọn baba wa pẹlu: ki ẹnyin ki o le joko ni ilẹ Goṣeni; nitori irira li oluṣọ-agutan gbogbo si awọn ara Egipti.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
ẹ fún-un lésì pé, “àwọn ìránṣẹ́ rẹ ń tọ́jú ẹran-ọ̀sìn ni láti ìgbà ewe wa wá gẹ́gẹ́ bí a ṣe ba a lọ́wọ́ àwọn baba wa.” Nígbà náà ni wọn yóò fún un yín láàyè láti tẹ̀dó sí ilẹ̀ Gósénì. Nítorí pé àwọn ará Éjíbítì kóríra ẹnikẹ́ni tí ó bá jẹ́ darandaran.