Genesis 47:11 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Josẹfu bá fi baba ati àwọn arakunrin rẹ̀ sí ibi tí ó dára jùlọ ní ilẹ̀ Ijipti, ninu ilẹ̀ Ramesesi, gẹ́gẹ́ bí Farao ti pa á láṣẹ.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Josefu si fi baba rẹ̀ ati awọn arakunrin rẹ̀ joko, o si fun wọn ni iní ni ilẹ Egipti, ni ibi ãyo ilẹ, ni ilẹ Ramesesi, bi Farao ti pa li aṣẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Joṣẹ́fù sì fi baba rẹ̀ àti àwọn arákùnrin rẹ̀ sí ilẹ̀ Éjíbítì, ó sì fún wọn ní ohun-ìní ní ibi tí ó dára jù ní ilẹ̀ náà, ní agbégbé Ráméṣéṣì bí Fáráò ti pàṣẹ.