Genesis 47:14 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Gbogbo owó tí àwọn ará ilẹ̀ Ijipti ati àwọn ará ilẹ̀ Kenaani ní patapata ni wọ́n kó tọ Josẹfu wá láti fi ra oúnjẹ. Josẹfu sì kó gbogbo owó náà lọ fún Farao.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Josefu si kó gbogbo owo ti a ri ni ilẹ Egipti ati ni ilẹ Kenaani jọ, fun ọkà ti nwọn rà: Josefu si kó owo na wá si ile Farao.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Jósẹ́fù gba gbogbo owó tí ó wà ní ilẹ̀ Éjíbítì àti Kénánì ní ìpààrọ̀ fún ti ọkà tí wọn ń rà, ó sì mú owó náà wá sí ààfin Fáráò.