Genesis 47:17 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Wọ́n bá kó àwọn ẹran ọ̀sìn wọn tọ Josẹfu lọ, Josẹfu sì fún wọn ní oúnjẹ dípò àwọn ẹran ọ̀sìn wọn, agbo ẹran wọn, agbo mààlúù wọn ati kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ wọn. Ó fi àwọn ẹran ọ̀sìn wọn dí oúnjẹ fún wọn ní ọdún náà.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nwọn si mú ẹran wọn tọ̀ Josefu wá: Josefu si fun wọn li onjẹ dipò ẹṣin, ati ọwọ́-ẹran, ati dipò ọwọ́-malu, ati kẹtẹkẹtẹ: o si fi onjẹ bọ́ wọn dipò gbogbo ẹran wọn li ọdún na.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nítorí náà wọ́n mú àwọn ẹran-ọ̀sìn wọn tọ Jósẹ́fù wá, ó sì fún wọn ní oúnjẹ ní ìpààrọ̀ fún ẹsin, àgùntàn, ewúrẹ́, màlúù àti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ wọn. Ó sì mú wọn la ọdún náà já, tí ó ń fún wọn ní oúnjẹ ní ìpààrọ̀ fún ẹran-ọ̀sìn wọn.