Genesis 47:18 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nígbà tí ọdún náà parí, wọ́n tún wá sọ́dọ̀ Josẹfu ní ọdún keji, wọ́n ní, “A kò jẹ́ purọ́ fún oluwa wa, pé kò sí owó lọ́wọ́ wa mọ́ rárá, gbogbo agbo ẹran wa sì ti di tìrẹ, a kò ní ohunkohun mọ́ àfi ara wa ati ilẹ̀ wa.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbati ọdún na si pari, nwọn si tọ̀ ọ wá li ọdún keji, nwọn si wi fun u pe, Awa ki yio pa a mọ́ lọdọ oluwa mi, bi a ti ná owo wa tán; ẹran-ọ̀sin si ti di ti oluwa mi; kò si sí nkan ti o kù li oju oluwa mi, bikoṣe ara wa, ati ilẹ wa:
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà tí ọdún náà parí, wọn padà tọ̀ ọ́ wá ní ọdún tí ó tẹ̀le, wọn wí pé, “A kò le fi pamọ́ fun olúwa wa pé níwọ̀n bí owó wa ti tan tí gbogbo ẹran-ọ̀sìn wa sì ti di tirẹ̀ pé, kò sí ohunkóhun tó kù fún olúwa wa bí kò ṣe ara wa àti ilẹ̀ wa.