Genesis 47:19 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ǹjẹ́ o lè máa wò wá níran títí tí a óo fi kú, ati àwa, ati ilẹ̀ wa? Fi oúnjẹ ra àwa ati ilẹ̀ wa, a óo sì di ẹrú Farao. Fún wa ní irúgbìn, kí á lè wà láàyè, kí ilẹ̀ yìí má baà di ahoro.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitori kili awa o ṣe kú li oju rẹ, ati awa ati ilẹ wa? fi onjẹ rà wa ati ilẹ wa, ati awa ati ilẹ wa yio ma ṣe ẹrú Farao: ki o si fun wa ni irugbìn, ki awa ki o le yè, ki a má kú, ki ilẹ ki o má ṣe di ahoro.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Èése tí àwa yóò fi parun lójú rẹ, ra àwa tìkárawa àti ilẹ̀ wa ní ìpààrọ̀ fún oúnjẹ, àwa àti ilẹ̀ wa yóò sì wà nínú ìgbékùn Fáráò. Fún wa ni oúnjẹ kí àwa kí ó má ba à kú, kí ilẹ̀ wa má ba à di ahoro.”