Genesis 47:20 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Josẹfu bá ra gbogbo ilẹ̀ Ijipti fún Farao, nítorí pé gbogbo àwọn ará Ijipti ni wọ́n ta ilẹ̀ wọn, nítorí ìyàn náà dà wọ́n láàmú pupọ. Bẹ́ẹ̀ ni gbogbo ilẹ̀ Ijipti ṣe di ti Farao,
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Bẹ̃ni Josefu rà gbogbo ilẹ Egipti fun Farao; nitori olukuluku awọn ara Egipti li o tà oko rẹ̀, nitori ti ìyan na mú wọn: ilẹ si di ti Farao.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nítorí náà Jósẹ́fù ra gbogbo ilẹ̀ tí ó wà ní Éjíbítì fún Fáráò, kò sí ẹnìkan tí ó sẹ́kù ní Éjíbítì tí kò ta ilẹ̀ tirẹ̀ nítorí ìyàn náà mú jù fún wọn. Gbogbo ilẹ̀ náà sì di ti Fáráò,