Genesis 47:22 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Àfi ilẹ̀ àwọn babalóòṣà nìkan ni kò rà, nítorí pé ó ní iye tí Farao máa ń fún wọn nígbàkúùgbà. Ohun tí Farao ń fún wọn yìí ni wọ́n sì fi ń jẹun. Ìdí nìyí tí kò jẹ́ kí wọ́n ta ilẹ̀ wọn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Kìki ilẹ awọn alufa ni kò rà; nitori ti awọn alufa ní ipín ti wọn lati ọwọ́ Farao wá, nwọn si njẹ ipín wọn ti Farao fi fun wọn; nitorina ni nwọn kò fi tà ilẹ wọn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣùgbọ́n sá, kò ra ilẹ̀ àwọn àlùfáà, nítorí wọ́n ń gba ìpín oúnjẹ lọ́wọ́ Fáráò, wọn sì ní oúnjẹ tí ó tó láti inú ìpín tí Fáráò ń fún wọn. Ìdí nìyí tí wọn kò fi ta ilẹ̀ wọn.