Genesis 47:24 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nígbà tí ẹ bá kórè, ẹ óo pín gbogbo ohun tí ẹ bá kórè sí ọ̀nà marun-un, ìpín kan jẹ́ ti Farao, ìpín mẹrin yòókù yóo jẹ́ tiyín. Ninu rẹ̀ ni ẹ óo ti mú irúgbìn, ati èyí tí ẹ óo máa jẹ, ẹ̀yin ati gbogbo ìdílé yín pẹlu àwọn ọmọ yín.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Yio si se, ni ikore ki ẹnyin ki o fi ida-marun fun Farao, ọ̀na mẹrin yio jẹ́ ti ara nyin fun irugbìn oko, ati fun onjẹ nyin, ati fun awọn ara ile nyin, ati onjẹ fun awọn ọmọ nyin wẹrẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣùgbọ́n nígbà tí ire oko náà bá jáde, ẹ ó mú ìdá kan nínú ìdá márùn-ún rẹ̀ fún Fáráò. Ẹ le pa ìdá mẹ́rin tókù mọ́ fún ara yín àti ìdílé yín àti àwọn ọmọ yín.”