Genesis 47:26 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Bẹ́ẹ̀ ni Josẹfu ṣe sọ ọ́ di òfin ní ilẹ̀ Ijipti, tí ó sì wà títí di òní olónìí pé ìdámárùn-ún gbogbo ìkórè oko jẹ́ ti Farao, ati pé ilẹ̀ àwọn babalóòṣà nìkan ni kì í ṣe ti Farao.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Josefu si ṣe e ni ilana ni ilẹ Egipti titi di oni-oloni pe, Farao ni yio ma ní idamarun; bikoṣe ilẹ awọn alufa nikan ni kò di ti Farao.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nítorí náà Jósẹ́fù sọ ọ́ di òfin nípa ọ̀rọ̀ ilẹ̀ ni Éjíbítì, ó sì wà bẹ́ẹ̀ di òni olónìí-pé, ìdá kan nínú ìdá márùn-ún irè oko jẹ́ ti Fáráò, ilẹ̀ àwọn àlùfáà nìkan ni kò di ti Fáráò.