Genesis 47:30 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
ṣugbọn gbé mi kúrò ní ilẹ̀ Ijipti kí o sì sin mí sí ibojì àwọn baba mi. Ibi tí wọ́n sin wọ́n sí ni mo fẹ́ kí o sin èmi náà sí.” Josẹfu dáhùn, ó ní, “Mo gbọ́, n óo ṣe bí o ti wí.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ṣugbọn nigbati emi ba sùn pẹlu awọn baba mi, iwọ o gbe mi jade ni Egipti, ki o si sin mi ni iboji wọn. On si wipe, Emi o ṣe bi iwọ ti wi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣùgbọ́n, nígbà tí mo bá sinmi pẹ̀lú àwọn baba mi, gbé mí jáde kúrò ní Éjíbítì kí o sì sin mí sí ibi tí wọ́n sin àwọn baba mi sí.” Jóṣẹ́fù sì dáhùn wí pé, “Èmi ó ṣe bí ìwọ ti wí.”