Genesis 48:1 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Lẹ́yìn náà, wọ́n sọ fún Josẹfu pé ara baba rẹ̀ kò yá, Josẹfu bá mú àwọn ọmọ rẹ̀ mejeeji, Manase ati Efuraimu, lọ́wọ́ lọ bẹ baba rẹ̀ wò.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O SI ṣe lẹhin nkan wọnyi ni ẹnikan wi fun Josefu pe, Kiyesi i, ara baba rẹ kò dá: o si mú awọn ọmọ rẹ̀ mejeji, Manasse ati Efraimu pẹlu rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Lẹ́yìn ìgbà díẹ̀ si, a wí fún Jósẹ́fù pé, “Baba rẹ ń sàìsàn,” nítorí náà, ó mú àwọn ọmọ rẹ̀ méjèèjì, Mánásè àti Éfúráímù lọ́wọ́ lọ pẹ̀lú rẹ̀.