Genesis 48:10 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ogbó ti mú kí ojú Israẹli di bàìbàì ní àkókò yìí, kò sì ríran dáradára mọ́. Josẹfu bá kó wọn súnmọ́ baba rẹ̀, baba rẹ̀ dì mọ́ wọn, ó sì fi ẹnu kò wọ́n lẹ́nu.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Njẹ oju Israeli ṣú baìbai nitori ogbó, kò le riran. On si mú wọn sunmọ ọdọ rẹ̀: o si fi ẹnu kò wọn li ẹnu, o si gbá wọn mọra.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Báyìí, ojú Ísírẹ́lì ti ń di bàìbàì nítorí ogbó, agbára káká sì ni ó fi ń ríran. Jósẹ́fù sì kó àwọn ọmọ rẹ̀ súnmọ́ ọ̀dọ̀ rẹ̀, baba rẹ̀ fẹnu kò wọ́n ni ẹnu, ó sì dì mọ́ wọn.