Genesis 48:16 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
kí angẹli tí ó yọ mí ninu gbogbo ewu bukun wọn; kí ìrántí orúkọ mi, ati ti Abrahamu, ati ti Isaaki, àwọn baba mi, wà ní ìran wọn títí ayé, kí atọmọdọmọ wọn pọ̀ lórí ilẹ̀ ayé.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Angeli na ti o dá mi ni ìde kuro ninu ibi gbogbo, ki o gbè awọn ọmọde wọnyi; ki a si pè orukọ mi mọ́ wọn lara, ati orukọ Abrahamu ati Isaaki awọn baba mi; ki nwọn ki o si di ọ̀pọlọpọ lãrin aiye.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ańgẹ́lì tí ó ti gbà mí kúrò lọ́wọ́ gbogbo ewu, kí ó súre fún àwọn ọmọkùnrin wọ̀nyí. Kí a máa fi orúkọ́ mi pè wọ́n àti orúkọ àwọn baba mi Ábúráhámù àti Ísáákì, kí wọn kí ó sì pọ̀ sí i lọ́pọ̀lọpọ̀ lórí ilẹ̀ ayé.”