Genesis 48:19 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ṣugbọn baba rẹ̀ kọ̀, ó ní, “Mo mọ̀, ọmọ mi, mo mọ̀, òun náà yóo di eniyan, yóo sì di alágbára, ṣugbọn sibẹsibẹ àbúrò rẹ̀ yóo jù ú lọ, àwọn ọmọ ọmọ rẹ̀ yóo sì di ọpọlọpọ orílẹ̀ èdè.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Baba rẹ̀ si kọ̀, o si wipe, Emi mọ̀, ọmọ mi, emi mọ̀: on pẹlu yio di enia, yio si pọ̀ pẹlu: ṣugbọ́n nitõtọ aburo rẹ̀ yio jù u lọ, irú-ọmọ rẹ̀ yio si di ọ̀pọlọpọ orilẹ-ède.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣùgbọ́n baba rẹ̀ kò gbà, ó wí pé, “Mo mọ̀, ọmọ mi, mo mọ̀. Òun náà yóò di orílẹ̀-èdè, òun náà yóò sì di ńlá. Ṣùgbọ́n àbúrò rẹ̀ yóò di ẹni ńlá jù ú lọ, irú ọmọ rẹ yóò sì di ọ̀pọ̀lọpọ̀ orílẹ̀-èdè.”