Genesis 48:5 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
“Tèmi ni àwọn ọmọkunrin mejeeji tí o bí ní ilẹ̀ Ijipti kí n tó dé, bí Reubẹni ati Simeoni ti jẹ́ tèmi, bẹ́ẹ̀ náà ni Manase ati Efuraimu jẹ́ tèmi.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Njẹ nisisiyi Efraimu ati Manasse, awọn ọmọ rẹ mejeji ti a bí fun ọ ni ilẹ Egipti, ki emi ki o tó tọ̀ ọ wá ni Egipti, ti emi ni nwọn: bi Reubeni on Simeoni, bẹ̃ni nwọn o jẹ́ ti emi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Nítorí náà báyìí, àwọn ọmọ rẹ méjèèjì tí a bí fún ọ ní ilẹ̀ Éjíbítì, kí èmi kí ó tó tọ̀ ọ́ wá ní ìhín, ni mo sọ di ọmọ mi fúnra mi. Mánásè àti Éfúráímù yóò jẹ́ tèmi gẹ́gẹ́ bí Rúbẹ́nì àti Símónì ti jẹ́ tèmi.