Genesis 48:9 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Josẹfu dá baba rẹ̀ lóhùn, ó ní, “Àwọn ọmọ mi, tí Ọlọrun pèsè fún mi níhìn-ín ni wọ́n.” Jakọbu bá wí fún un pé, “Jọ̀wọ́, jẹ́ kí wọ́n súnmọ́ mi kí n lè súre fún wọn.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Josefu wi fun baba rẹ̀ pe, Awọn ọmọ mi ni, ti Ọlọrun fifun mi nihinyi. O si wipe, Emi bẹ̀ ọ, mú wọn wá sọdọ mi, emi o si sure fun wọn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Jósẹ́fù fún baba rẹ̀ lésì pé, “Wọ̀nyí ni àwọn ọmọkùnrin tí Ọlọ́run ti fi fún mi ní ìhín.” Nígbà náà ni Ísírẹ́lì wí pé, “Kó wọn wá sí ọ̀dọ̀ mi kí èmi kí ó baà le súre fún wọn.”