Genesis 49:24 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
sibẹsibẹ ọrùn rẹ̀ kò mì, apá rẹ̀ sì ń lágbára sí i. Agbára Ọlọrun Jakọbu ni ó fún apá rẹ̀ ní okun, (ní orúkọ Olùṣọ́-aguntan náà, tí í ṣe Àpáta ààbò Israẹli),
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ṣugbọn ọrun rẹ̀ joko li agbara, a si mú apa ọwọ́ rẹ̀ larale, lati ọwọ́ Alagbara Jakobu wá, (lati ibẹ̀ li oluṣọ-agutan, okuta Israeli,)
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣùgbọ́n ọrun rẹ̀ dúró ni agbára, ọwọ́ agbára rẹ̀ ni a sì mu lára le, nítorí ọwọ́ alágbára Jákọ́bù, nítorí olútọ́jú àti aláàbò àpáta Ísírẹ́lì.