Genesis 49:25 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ọlọrun baba rẹ yóo ràn ọ́ lọ́wọ́. Ọlọrun Olodumare yóo rọ òjò ibukun sórí rẹ láti òkè ọ̀run wá, yóo sì fún ọ ní ibukun omi tí ó wà ní ìsàlẹ̀ ilẹ̀, ati ọpọlọpọ ọmọ ati ọpọlọpọ ẹran ọ̀sìn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ani lati ọwọ́ Ọlọrun baba rẹ wá, ẹniti yio ràn ọ lọwọ; ati lati ọwọ́ Olodumare wá, ẹniti yio fi ibukún lati oke ọrun busi i fun ọ, ibukún ọgbun ti o wà ni isalẹ, ibukún ọmú, ati ti inu.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nítorí Ọlọ́run baba rẹ tí ó ràn ọ́ lọ́wọ́, nítorí Olódùmarè tí ó bù kún ọ, pẹ̀lú láti ọ̀run wá, ìbùkún ọ̀gbìn tí ó wà ní ìṣàlẹ̀, ìbùkún ti ọmú àti ti inú,