Genesis 49:30 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ihò òkúta yìí wà ninu pápá ní Makipela, ní ìhà ìlà oòrùn Mamure ní ilẹ̀ Kenaani. Lọ́wọ́ Efuroni ará Hiti ni Abrahamu ti rà á pọ̀ mọ́ ilẹ̀ náà, kí ó lè rí ibi fi ṣe itẹ́ òkú.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ninu ihò ti o mbẹ ninu oko Makpela ti mbẹ niwaju Mamre, ni ilẹ Kenaani, ti Abrahamu rà pẹlu oko lọwọ Efroni, ara Hitti fun ilẹ-isinku.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ihò àpáta tí ó wà ní ilẹ̀ Mákípélà, nítòsí Mámúrè ní Kénánì, èyí tí Ábúráhámù rà gẹ́gẹ́ bí ilẹ̀-ìsìnkú lọ́wọ́ Éfúrónì ará Hétì pẹ̀lú ilẹ̀ rẹ̀.