Genesis 49:4 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ìwọ tí o dàbí ìkún omi tí ń bì síwá sẹ́yìn, o kò ní jẹ́ olórí, nítorí pé o ti bá obinrin mi lòpọ̀, o sì ti sọ ibùsùn èmi baba rẹ di aláìmọ́.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ẹnirirú bi omi, iwọ ki yio le tayọ; nitori ti iwọ gùn ori ẹni baba rẹ; iwọ si bà a jẹ́: o gùn ori akete mi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ẹni ríru bí omi òkun, ìwọ kì yóò tayọ mọ́, nítorí pé ìwọ gun ibùsùn baba rẹ, lórí àkéte mi, ìwọ sì bà á jẹ́ (ìwọ bá ọ̀kan nínú àwọn aya baba rẹ lò pọ̀).