Genesis 49:6 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Orí mi má jẹ́ kí n bá wọn pa ìmọ̀ pọ̀, ẹlẹ́dàá mi má sì jẹ́ kí n bá wọn kẹ́gbẹ́. Nítorí wọn a máa fi ibinu paniyan, wọn a sì máa ṣá akọ mààlúù lọ́gbẹ́ bí ohun ìdárayá.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ọkàn mi, iwọ máṣe wọ̀ ìmọ wọn; ninu ajọ wọn, ọlá mi, máṣe bá wọn dàpọ; nitoripe, ni ibinu wọn nwọn pa ọkunrin kan, ati ni girimakayi wọn, nwọn já malu ni patì.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Kí ọkàn mi má ṣe ni àṣepọ̀ pẹ̀lú wọn, kí n má sì ṣe dúró níbí ìpéjọpọ̀ wọn, nítorí wọ́n ti pa àwọn ènìyàn ní ìbínú wọn, wọ́n sì da àwọn màlúù lóró bí ó ti wù wọ́n.