Genesis 50:11 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nígbà tí àwọn ará Kenaani tí wọn ń gbé ibẹ̀ rí i bí wọ́n ti ń ṣọ̀fọ̀ ní ibi ìpakà náà, wọ́n wí pé, “Òkú yìí mà kúkú dun àwọn ará Ijipti o!” Nítorí náà, wọ́n sọ ibẹ̀ ní Abeli Misiraimu, ó wà ní apá ìlà oòrùn odò Jọdani.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbati awọn ara ilẹ na, awọn ara Kenaani, si ri ọ̀fọ na ni ibi ilẹ ipakà Atadi, nwọn wipe, Ọ̀fọ nla li eyi fun awọn ara Egipti: nitorina ni nwọn ṣe sọ orukọ rẹ̀ ni Abel-misraimu, ti o wà loke odò Jordani.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà tí àwọn ará Kénánì tí ń gbé níbẹ̀ ri i bí wọ́n ti ń sọ̀fọ̀ náà ni ilẹ̀ ìpakà Átadì, wọ́n wí pé, “Ọ̀fọ̀ ńlá ni àwọn ará Éjíbítì ń ṣe yìí.” Ìdí èyí ni a fi ń pe ibẹ̀ ní Abeli-Mísíráímù (Ìsọ̀fọ̀ àwọn ará Éjíbítì). Kò sì jìnnà sí Jọ́dánì.