Genesis 50:13 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Wọ́n gbé òkú rẹ̀ lọ sí ilẹ̀ Kenaani, wọ́n sì sin ín sinu ihò òkúta tí ó wà ninu oko Makipela, ní ìhà ìlà oòrùn Mamure, tí Abrahamu rà mọ́ ilẹ̀ tí ó rà lọ́wọ́ Efuroni ará Hiti láti fi ṣe itẹ́ òkú.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitori ti awọn ọmọ rẹ̀ mú u lọ si ilẹ Kenaani, nwọn si sin i ninu ihò oko Makpela, ti Abrahamu rà pẹlu oko fun iní ilẹ isinku, lọwọ Efroni ara Hitti, niwaju Mamre.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Wọ́n gbé e lọ sí ilẹ̀ Kénánì, wọ́n sì sin-ín sínú ihò àpáta tí ó wà ní oko Makipélà, ní tòsí i Mámúrè tí Ábúráhámù rà gẹ́gẹ́ bí ilẹ̀ ìsìnkú lọ́wọ́ Éfúrónì ará Hítì, pẹ̀lú ilẹ̀ náà.