Genesis 50:14 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nígbà tí Josẹfu sin òkú baba rẹ̀ tán, ó pada lọ sí ilẹ̀ Ijipti pẹlu àwọn arakunrin rẹ̀, ati gbogbo àwọn tí wọ́n bá a lọ.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Josefu si pada wá si Egipti, on ati awọn arakunrin rẹ̀, ati gbogbo awọn ti o bá a goke lọ lati sin baba rẹ̀, lẹhin ti o ti sin baba rẹ̀ tán.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Lẹ́yìn ìgbà tí ó ti sìnkú baba rẹ̀ tan, Jóṣẹ́fù padà sí Éjíbítì pẹ̀lú àwọn arákùnrin rẹ̀ àti àwọn mìíràn tí ó tẹ̀lé e lọ láti sin baba rẹ̀.