Genesis 50:17 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
‘Ẹ sọ fún Josẹfu pé, dárí àṣìṣe ati ẹ̀ṣẹ̀ àwọn arakunrin rẹ jì wọ́n, nítorí wọ́n ṣe ibi sí ọ.’ ” Wọ́n bá bẹ̀rẹ̀ sí bẹ̀ ẹ́ pé, “Jọ̀wọ́, dárí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn iranṣẹ Ọlọrun baba rẹ jì wọ́n.” Nígbà tí Josẹfu gbọ́ ọ̀rọ̀ yìí, ó bú sẹ́kún.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Bayi ni ki ẹnyin wi fun Josefu pe, Njẹ emi bẹ̀ ọ, dari irekọja ati ẹ̀ṣẹ awọn arakunrin rẹ jì wọn, nitori ibi ti nwọn ṣe si ọ. Njẹ nisisiyi, awa bẹ̀ ọ, dari irekọja awọn iranṣẹ Ọlọrun baba rẹ jì wọn. Josefu si sọkun nigbati nwọn sọ fun u.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
‘Èyí ni kí ẹ̀yin kí ó sọ fún Jóṣẹ́fù: Mo bẹ̀ ọ́ kí o dáríjìn àwọn arákùnrin rẹ, gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ àti aburú tí wọ́n ṣe sí ọ, èyí tí ó mú ibi bá ọ’. Nísinsin yìí, jọ̀wọ́ dárí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run baba rẹ jìn wọ́n.” Nígbà tí iṣẹ́ ti wọ́n rán dé ọ̀dọ̀ rẹ̀, Jósẹ́fù sunkún.