Genesis 50:2 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Lẹ́yìn náà, Josẹfu pàṣẹ fún àwọn iranṣẹ rẹ̀ tí wọn ń ṣiṣẹ́ ìṣègùn pé kí wọ́n fi òògùn tí wọ́n fi máa ń tọ́jú òkú, tí kì í fíí bàjẹ́, tọ́jú òkú baba òun. Wọ́n fi òògùn yìí tọ́jú òkú Jakọbu.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Josefu si paṣẹ fun awọn iranṣẹ rẹ̀, awọn oniṣegun, ki nwọn ki o kùn baba on li ọṣẹ: awọn oniṣegun si kùn Israeli li ọṣẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà náà ni Jósẹ́fù pàṣẹ fún àwọn oníṣègùn tí ó wà ní ìkáwọ́ rẹ̀ pé kí wọn kí ó ṣe òkú Ísírẹ́lì baba rẹ̀ lọ́jọ̀, àwọn oníṣègùn náà sì ṣe bẹ́ẹ̀,